Apeke Kan, Iwo Kan Poem by Sab O. Ibrahim

Apeke Kan, Iwo Kan

Rating: 5.0

Ololufemi owon,
Apeke Omo Olode Okuta,
Olori laafin Akanmu,
Omobukola Arewa,
Omo oni iwa tutu bi odo oba...

Haolatu Aya Akanmu,
Obinrin rere lode Oko,
Omo Oje Moin-Moin dari j'ewe,
Omo bi ebi ba n pani Ounje laaje,
Ogidi Omo Ile Ajijagun Esin,
Omo Omo Oluko Agba,
Fadheelatu Shaykh AbdulBaaki Muhammad,
Ki Olohun ba wa tewon s'afefe re,
Apeke kan, Iwo kan!

Apeke Odi,
Omo Iwo olodo Oba,
Omo ateni gbola,
teni gbore nile awon eni ire,
Omo oge gele mu omi Imo,
Akoja ewe Al-Mogaji Olomoyoyo,
Omo re bi iyan,
Omo to dun bi Oyin,
Apeke kan, Iwo Kan...

Ife re n da mi lo run gidi-gan,
Ife re osi la fi we ojie,
sure tete ki o je mi ni o',
Sure tete ki o pada wa le,
Otutu Ife re n pami ku lo,
Wa raga bomi bi Angeli Oluwa wa,
Je omi tuntun ru ninu aye wa,
Iwo leni bi Okan mi,
Ayanfe mi, la torun wa,
MO NI Ife re Gidi-gan ni o,
Apeke kan, Iwo kan....

Thursday, September 29, 2016
Topic(s) of this poem: unconditional love
POET'S NOTES ABOUT THE POEM
That's my first ever poem written in Yoruba, and it's fittingly dedicated to my TREASURED QUEEN; Abdulbaaki Haolat Apeke)
COMMENTS OF THE POEM
READ THIS POEM IN OTHER LANGUAGES
Sab O. Ibrahim

Sab O. Ibrahim

Lagos State, Nigeria
Close
Error Success