Lọjọ Ti Iya Agba Sun Poem by Chukwuebuka Adebayo

Lọjọ Ti Iya Agba Sun

Omije t'oju mi poro-poro bọ silẹ
Lọ'jọ t'omo Moradehun lọ s'ọrun
Ọkan mi dabi ikooko ti a sọ lulẹ,
Nigba mo gbọ igbe Ẹkun l'ẹnu
L'ẹkun
Ti t'omode - t'agba fa 'juro,
Nigbati mo ri ọpọ-eniyan bi
ọwara-ojo
Ti wọn ng yọ kẹlẹ lọ wo mọnria
ni koto.
.
.
.
Se bo 'ba gbejẹ, iwọ afẹfẹ ti
'nrọ,
Ki o ma se si ariwo tabi kikun
Bi ko se ti ewe-igi ti o ng wọ
Jẹ ki gbogbo ẹiyẹ oko dakẹ
didun
Ọmọ eniyan i ba siwọ pakaleke
diẹ
Ẹ jẹ ng se daro, atupa ti o subu
lulẹ
Ti ile fi dabi ahoro inu erupẹ.
.
.
.
Awọ osumare ti o di akisa
Ko sẹyin ojiji ti o bo sannmọn
Ookun duuru olohun didun ti oja
Ti orin fi dabi ariwo ọmọde ti ng
han
Ẹ jẹ ng se 'daro, ẹ jẹ ng kẹdun,
Alanu kan ti o lọ s'ọrun
Iya mi agba, mọnria-moradehun.
.
.
Mo ni ẹ mọn sọrọ iku, e mi o beru,
Igbin tori iku sọra ẹ si ikarahun,
Agbọn sọra ẹ d'omo iya ẹtu,
O se bi ibọn le pa iku.Yerepe
f'ẹgun
Sin gbẹrẹ tori iku buruku tin pa
ni,
O gbagbe faka-fiki 'ji,
At'agbara ti ng gbe gbogbo 'gi.
.
.
.
Mo ni kilode ti ọmọ ẹda fin sun,
Ni wọn gba ti wọn o tun ji pada?
Kilode ti ọmọ eniyan fi ng
sunkun,
B'ojumọ eni ba re 'walẹ-asa?
Bi enipe a o ni pada gbe wa dide,
Ko ba jẹ 'ya sare lọ irinajo eti-ile
Ng o ba kuku ma reti ọjọ ti iya
oode.
.
.
.
Sugbọn iku wole, O mu ẹnire Lọ,
A kuku bẹ 'ku, iku o gbọran, iku
fariga
O ni gbogbo igi lo dara ni'ju
lotỌọ
Sugbon tani ninu awọn ọmọ ẹda
Ti ng jẹ pade ododo lẹ 'ba ọna,
Ti yio asi fi silẹ lalai ja,
Tabi ọwọn goolu ti yio f'ẹsẹ re
kọja?
.
.
.
Ki lẹ o fi se 'diwọn fun mi?
Ki lo le tẹ'ja l'ọrun bi omi?
Tabi ọmọ-ẹyẹ l'ọrun bi 'gi?
Mo ni o dabi eemi ti mo un mi
O ju ti ifẹnu-konu eniyan lỌọ
Kini o le da bi ololufe mi otitọ,
Ta 'lo le se bi iya-agba tabi ti yio
jọ?
.
.
.
Iya onidodo olododo,
O fi ran sẹ si wọn loko
Gbogbo ero oko fun lowo;
O ta dodo fun wọn l'eko,
O fi fọkọ f'ọmọ rẹ f'ara eko
Ọmọ olore, ti f'awo b'omi f'ọrẹ
lodo
Ọmọ akin bi asa, ti o gbọdọ sa
fun riruu odo.
.
.
.
Sun re o, ọmọ wọn ni'le Lẹẹsi,
Olojo tayẹ mọnbọ, ẹẹlẹrin ẹwẹlẹ
O f'ẹrin s'ẹfin di'na.Iwọ lo fi
Ifẹ s'ẹru d'omo a un pe sayẹyẹ
Itura atẹgun ti lana ni'ju fu'ọmọ
Ọde
Idunu ojo ti m'ara gbogbo ewe-
oko dẹ
Anu kurukuru ti ba 'gi igbo wo
gbogbo ọgbẹ.
.
.
.
Maa sun, Olufẹ,
Maa sinmi, k'oo si maa gbadun
Ni'bi ti ko si ẹkun diẹ, ẹrin diẹ
Ni'bi ti iro iji lile kii ti dun,
Ni'bi ti ko si aarọ, tabi aalẹ
Ni'bi ti ogo ti ng dun kẹ kẹ kẹ
Ti ewe-ododo sin fẹ lẹ lẹ lẹ lẹ lẹ.
o d'arọ o.

Wednesday, December 28, 2016
Topic(s) of this poem: death
POET'S NOTES ABOUT THE POEM
Ewi yi.this lines is dedicated to our grandgreatmother, grandmother.wife, sister, friend.Deaconess Maria Moradehun who died at age of 80 and was buried at her hometown #Ikire, Osun state, Nigeria.SLEEP MAMA.I sorry this is all i could give to show my love to you. Composed by Sir toby @2016.
COMMENTS OF THE POEM
READ THIS POEM IN OTHER LANGUAGES
Close
Error Success