Ojo onikuloye
Akọni ọmọde t'agba ole rẹjẹ
Tani je apefọn níwájú apayan?
Ojo osi ni ilẹ, ọmọ ọlẹ sagbara
Agbara wa, ogun po bi yepẹ etido
Ojo ku wuruwuru bi ojo anaa
Omi agbe sìn bẹ lamù
Ati kekere loti ya igboju ọmọ
Iwin ọmọ ti gbe 'bọn rin l'ọsan gan
Ẹbọra Oru ti komọn eni ọwọ
Lomu mi rántí ọjọ meriri
Ojo fi ipa gba bọn lọwọ soja ọmọ ọdẹ
Ti o sọ gbogbo ìlú ìkirè sí bolọ o -sé- mi
Gbogbo ọjà l'oda koko, o di ẹni láyà obo de,
Tani o ni ohun omon asin?
Bó ba dekute mọn, o gbọ orun bi?
Ojo wa dẹni awọn agbofinro wo loke tente
Bi ẹ ba sebẹ mun ọran ojo dé sitasan
Won àní, ẹ ma da ọmọ ojo yẹn lohun
Ojo wa di, ẹ ni aà ba lemu afa le oba oke lọwọ
Ọjọ ti pẹ ilẹ tin gbe osika
Kori ẹni ma sa f'ẹni silẹ
Ọjọ ajá bati gbero ati yi balangada
Nijọ awọn ọbọ, lẹtẹ ti dé ba
Ọjọ ayan bati feyin kule adire se
Pápá iṣere, niyonu dé ba alakori
Wọn wí f'ojo pe ko ṣọra se
Sugbọn Ojo o leti ọrọ.
Ojo, ọmọ nla lagbọ pe awọn kan le nipa
Wọn mú bi ẹyẹ ti o lapa mọn
Ti wọn sì ṣá pa mọn lẹ
Sugbọn ohun to dami loju nipé,
Ibi akọni ba ti kọsẹ toku sí,
A je wipe ẹlẹdàá ẹ loti subu.
This poem has not been translated into any other language yet.
I would like to translate this poem