Pamin'kú!(I)
O si fi suuru se ẹsọ;
K'ọbẹ ton nyọ bọlọ,
Le to ọ jẹun?
Ìjà loni l'ọla, jaga-jìgì
Ti mu ọ ru pẹlẹbẹ
O da bi aja ti nse aisan.
Bi ko ba si Nile, (ii)
A dabi pe a ko akisà kurò n'iná
Bi o ba wa l'òọdẹ
Òdẹdẹ a paiya sókè
Bi atẹgun lile tiko rọjò.
Ōkọ ẹrù, Àlè ijamba
Gbogbo ẹbí ọkọ ni ofẹ ọ ri.
Ilẹkun ile wọn-a ro gbámùún, (iii)
Irọkẹkẹ, hilàhilo l'ọsan, l'oru
O ti sọ ara ẹ di asíwín;
A ma dasọ bi ọràn igbo,
B'ọkọ wí ení, A wí ẹgbẹrun
Ojojumọn sáá ni ìjà ko ni'sīmī
Ariwo gè-è ki tan nile wọn.
Wọn -ran- wọn -ran, Ara o bálẹ(iv)
Ahọn rẹ-a jo bàlà-bàlà;
Enu rẹ-a ro pàkà-pàkà,
Irun ori ẹ dabi ti ọdajú ēléwọn
Orun-un mu-un, ẹgbin akitan ōkō
Alapa'ke o le wẹ f'ọmọ
De'bi ti yio ba fọ eyín ẹnū.
Awọn ọmọde tin yà fun ọ(V)
Bi ẹni yẹ fun ìjàlọ-èrùn,
Awọn iyawo'le a fi ọwọ t'ọra wọn
Bi o ba sèésì kọja l'ojúde.
Wọn-a p'òsé shùún-rún-shùún,
Awọn àgbà ā wo ọsù ù,
Wọn ní o ní'gberāgā.
Aigbẹkọ ni Akọ'gbà. (Vi)
Alọsọ-mọkọ-lọrun o lérè
Esọ pẹlẹ ni ko se ile-aye
Suru, itẹriba ni irin ajo aye gbà
Bi a ba pe'ni ni onifun raii-raii
Onifun na a si pa'fun ẹ mọn.
Pamin'kú obinrin, tunwa rẹ se.
.
.
©Sir toby
@tue, may 19 2020
This poem has not been translated into any other language yet.
I would like to translate this poem
this poem is prepared in Yoruba language.you may translate with Google if you want. Happy reading.